Jobu 19:22-27 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ọlọrun ń lépa mi,ẹ̀yin náà sì tún ń lépa mi!Kí ló dé tí ẹran ara mi kò to yín?

23. “À bá lè kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀!Àní, kí á kọ ọ́ sinu ìwé!

24. Kí á fi kálàmú irin ati òjékọ ọ́ sórí àpáta, kí ó wà níbẹ̀ títí lae.

25. Ṣugbọn mo mọ̀ pé Olùdáǹdè mi ń bẹ láàyè,ati pé, níkẹyìn, yóo dìde dúró lórí ilẹ̀ yóo sì jẹ́rìí mi,

26. lẹ́yìn tí awọ ara mi bá ti díbàjẹ́,ṣugbọn ninu ara mi ni n óo rí Ọlọ́run.

27. Fúnra mi ni n óo rí i,ojú ara mi ni n óo sì fi rí i,kì í ṣe ti ẹlòmíràn.“Ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì ninu mi!

Jobu 19