Jobu 19:17-25 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ iyawo mi,mo sì ń rùn sí àwọn ọmọ ìyá mi.

18. Àwọn ọmọde pàápàá ń fojú tẹmbẹlu mi;bí mo bá dìde wọn á máa sọ̀rọ̀ sí mi.

19. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti rí mi sá,àwọn tí mo nífẹ̀ẹ́ ti kẹ̀yìn sí mi.

20. Mo rù kan egungun,agbára káká ni mo fi sá àsálà.

21. Ẹ ṣàánú mi, ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi,nítorí ọwọ́ Ọlọrun ti bà mí!

22. Ọlọrun ń lépa mi,ẹ̀yin náà sì tún ń lépa mi!Kí ló dé tí ẹran ara mi kò to yín?

23. “À bá lè kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀!Àní, kí á kọ ọ́ sinu ìwé!

24. Kí á fi kálàmú irin ati òjékọ ọ́ sórí àpáta, kí ó wà níbẹ̀ títí lae.

25. Ṣugbọn mo mọ̀ pé Olùdáǹdè mi ń bẹ láàyè,ati pé, níkẹyìn, yóo dìde dúró lórí ilẹ̀ yóo sì jẹ́rìí mi,

Jobu 19