Jobu 19:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jobu bá dáhùn, ó ní,

2. “Ẹ óo ti ni mí lára pẹ́ tó,tí ẹ óo máa fi ọ̀rọ̀ yín bà mí ninu jẹ́?

3. Ẹ kẹ́gàn mi ní àìníye ìgbàojú kò tilẹ̀ tì yín láti ṣẹ̀ mí?

4. Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé lótìítọ́ ni mo ṣẹ̀,ṣebí ara mi ni àṣìṣe mi wà?

5. Bí ẹ bá rò pé ẹ sàn jù mí lọ,tí ẹ sì rò pé ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ni ìdààmú mi,

6. ẹ mọ̀ dájú pé Ọlọrun ni ó dá mi lẹ́bi,tí ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

7. Mò ń kérora pé wọ́n dá mi lóró,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn;mo pariwo, pariwo,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dìde láti ṣe ẹ̀tọ́.

8. Ọlọrun ti dí ọ̀nà mọ́ mi, kí n má baà kọjá,ó mú ọ̀nà mi ṣókùnkùn.

9. Ó bọ́ ògo mi kúrò,ó sì gba adé orí mi.

Jobu 19