Jobu 15:15-32 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Wò ó, Ọlọrun kò fọkàn tán àwọn angẹli,àwọn ọ̀run kò sì mọ́ níwájú rẹ̀.

16. Kí á má tilẹ̀ wá sọ ti eniyantí ó jẹ́ aláìmọ́ ati ẹlẹ́gbin,tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni mu omi!

17. “Fetí sílẹ̀, n óo sọ fún ọ,n óo sọ ohun tí ojú mi rí,

18. (ohun tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ,tí àwọn baba wọn kò sì fi pamọ́,

19. àwọn nìkan ni a fún ní ilẹ̀ náà,àlejò kankan kò sì sí láàrin wọn).

20. Ẹni ibi ń yí ninu ìrora ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,àní, ní gbogbo ọdún tí a là sílẹ̀ fún ìkà.

21. Etí rẹ̀ kún fún igbe tí ó bani lẹ́rù,ninu ìdẹ̀ra rẹ̀ àwọn apanirun yóo dìde sí i.

22. Kò gbàgbọ́ pé òun lè jáde kúrò ninu òkùnkùn;ati pé dájú, ikú idà ni yóo pa òun.

23. Ó ń wá oúnjẹ káàkiri, ó ń bèèrè pé,‘Níbo ló wà?’Òun gan-an sì nìyí, oúnjẹ àwọn igún!Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn ti súnmọ́ tòsí.

24. Ìdààmú ati ìrora dẹ́rùbà á,wọ́n ṣẹgun rẹ̀, bí ọba tí ó múra ogun.

25. Nítorí pé ó ṣíwọ́ sókè sí Ọlọrun,o sì ṣe oríkunkun sí Olodumare,

26. ó ń ṣe oríkunkun sí i,ó sì gbé apata tí ó nípọn lọ́wọ́ láti bá a jà;

27. nítorí pé ó sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú rẹ̀ yíbò,ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ kìkì ọ̀rá.

28. Ó ń gbé ìlú tí ó ti di ahoro,ninu àwọn ilé tí eniyan kò gbọdọ̀ gbé,àwọn ilé tí yóo pada di òkítì àlàpà.

29. Kò ní ní ọrọ̀,ohun tí ó bá ní, kò ní pẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,òun alára kò sì ní fìdí múlẹ̀.

30. Kò ní bọ́ kúrò ninu òkùnkùn,iná yóo jó àwọn ẹ̀ka rẹ̀,afẹ́fẹ́ yóo sì fẹ́ àwọn ìtànná rẹ̀ dànù.

31. Kí ó má gbẹ́kẹ̀lé òfo,kí ó má máa tan ara rẹ̀ jẹ,nítorí òfo ni yóo jẹ́ èrè rẹ̀.

32. A ó san án fún un lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lọ́jọ́ àìpé,gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ ni yóo sì gbẹ.

Jobu 15