21. Nítorí náà, n óo gbé ohun ìdínà sọ́nà fún àwọn eniyan wọnyi,wọn óo sì fẹsẹ̀ kọ;ati baba, àtọmọ wọn,àtaládùúgbò, àtọ̀rẹ́,gbogbo wọn ni yóo parun.”
22. OLUWA ní,“Wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,orílẹ̀-èdè ńlá ń gbéra bọ̀ láti òpin ayé.
23. Wọ́n ń kó ọrun ati ọ̀kọ̀ bọ̀,ìkà ni wọ́n, wọn kò sì lójú àánú.Ìró wọn dàbí híhó omi òkun,bí wọ́n ti ń gun ẹṣin bọ̀.Wọ́n tò bí àwọn tí ń lọ sójú ogun,wọ́n dótì ọ́, ìwọ Jerusalẹmu!”
24. A gbúròó wọn, ọwọ́ wa rọ;ìdààmú dé bá wa,bí ìrora obinrin tí ó ń rọbí.