Jeremaya 52:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba, ọdún mọkanla ni ó sì fi wà lórí oyè ní Jerusalẹmu. Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina ni ìyá rẹ̀.

2. Sedekaya ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bí Jehoiakimu ti ṣe.

3. Nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ ní Jerusalẹmu ati Juda burú débi pé inú fi bí OLUWA sí wọn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi tì wọ́n jáde kúrò níwájú rẹ̀.Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni.

4. Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa, ní ọdún kẹsan-an tí Sedekaya gorí oyè, Nebukadinesari, ọba Babiloni, dé sí Jerusalẹmu pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ yíká.

5. Wọ́n dóti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya.

Jeremaya 52