Jeremaya 48:11-22 BIBELI MIMỌ (BM)

11. OLUWA ní,“Láti ìgbà èwe Moabu ni ó ti ń gbé pẹlu ìrọ̀rùn,kò tíì lọ sí ìgbèkùn rí.Nítorí náà ó silẹ̀ bí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ọtí.A kò máa dà á kiri láti inú ìgò kan sí òmíràn.Adùn rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀, òórùn rẹ̀ kò sì tíì yipada.

12. “Nítorí náà, àkókò ń bọ̀,tí n óo jẹ́ kí wọn da Moabu nù, bí ẹni da ọtí nù.Àwọn tí wọn ń da ọtí nù ni n óo rán, tí wọn óo wá tẹ̀ ẹ́ bí ìgò ọtíwọn óo dà á nù patapata, wọn óo sì fọ́ ìgò rẹ̀.

13. Kemoṣi yóo di ohun ìtìjú fún Moabu,gẹ́gẹ́ bí Bẹtẹli, tí Israẹli gbójú lé, ṣe di ohun ìtìjú fún Israẹli.

14. Ẹ ṣe lè wí pé alágbára ni yín, ati pé ẹ jẹ́ akikanju lójú ogun?

15. Ẹni tí yóo pa ilẹ̀ Moabu ati àwọn ìlú rẹ̀ run ti dé,àwọn àṣàyàn ọmọkunrin rẹ̀ sì ti lọ sí ibi tí wọn ó ti pa wọ́n.Èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

16. Ọjọ́ ìdààmú Moabu fẹ́rẹ̀ dé, ìpọ́njú rẹ̀ sì ń bọ̀ kánkán.

17. “Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ dárò rẹ̀,kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ orúkọ rẹ̀ sì wí pé,‘Ọ̀pá àṣẹ tí ó lágbára ti kán,ọ̀pá àṣẹ tí ó lógo ti ṣẹ́.’

18. Sọ̀kalẹ̀ kúrò ninu ògo rẹ, kí o jókòó lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, ìwọ tí ò ń gbé Diboni!Nítorí pé ẹni tí óo pa Moabu run ti dojú kọ ọ́,ó sì ti wó àwọn ibi ààbò rẹ̀.

19. Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o máa ṣọ́nà, ìwọ tí ò ń gbé Aroeri!Bèèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n sálọ; bi àwọn tí ń sá àsálà pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀?’

20. Ìtìjú ti bá Moabu, nítorí pé ó ti wó lulẹ̀; ẹ kígbe, ẹ máa sọkún.Ẹ kéde rẹ̀ ní ipadò Anoni, pé,‘Moabu ti parẹ́, ó ti di òkítì àlàpà.’

21. “Ìdájọ́ ti dé sórí àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú: Holoni, Jahisai, ati Mefaati;

22. Diboni, Nebo, ati Beti Dibilataimu,

Jeremaya 48