1. OLUWA bá Jeremaya wolii sọ̀rọ̀ nípa Filistini kí Farao tó ṣẹgun Gasa,
2. Ó ní,“Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá,yóo di àgbàrá tí ó lágbára;yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
3. Nígbà tí pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin bá ń dún,tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ bá ń sáré,tí ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sì ń pariwo,Àwọn baba kò ní lè wo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn pé kí àwọn fà wọ́n,nítorí pé ọwọ́ wọn yóo rọ;