Jeremaya 46:23-28 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Wọn yóo gé igi inú igbó rẹ̀ lulẹ̀.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó náà dí,nítorí pé igi ibẹ̀ pọ̀ bí eṣú, tí wọn kò sì lóǹkà.

24. A óo dójú ti àwọn ará Ijipti,a óo fà wọ́n lé àwọn ará ìhà àríwá lọ́wọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

25. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: “N óo fi ìyà jẹ Amoni, oriṣa Tebesi, ati Farao, ati Ijipti pẹlu àwọn oriṣa rẹ̀, ati àwọn ọba rẹ̀. N óo fìyà jẹ Farao ati àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

26. N óo fà wọ́n lé àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́; n óo fà wọ́n fún Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan yóo máa gbé Ijipti bíi ti àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

27. “Ṣugbọn ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,ọmọ Israẹli, ẹ má fòyà;n óo gbà yín là láti ọ̀nà jíjìn,n óo kó arọmọdọmọ yín yọ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ óo pada máa gbé ní ìrọ̀rùn.Kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rù bà yín.

28. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,nítorí pé mo wà pẹlu yín.N óo run gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo le yín lọ,ṣugbọn n kò ní pa yín run.Bí ó bá tọ́ kí n jẹ yín níyà, n óo jẹ yín níyà,kìí ṣe pé n óo fi yín sílẹ̀ láìjẹ yín níyà.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Jeremaya 46