12. gbogbo àwọn ará Juda pada láti gbogbo ibi tí wọn sá lọ, wọ́n wá sí ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa, wọ́n sì kó ọtí ati èso jọ lọpọlọpọ.
13. Johanani ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko wá sọ́dọ̀ Gedalaya ní Misipa.
14. Wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Baalisi, ọba àwọn ọmọ Amoni ti rán Iṣimaeli, ọmọ Netanaya pé kí ó wá pa ọ́?” Ṣugbọn Gedalaya kò gbà wọ́n gbọ́.
15. Johanani bá sọ fún Gedalaya ní ìkọ̀kọ̀ ní Misipa pé, “Jẹ́ kí n lọ pa Iṣimaeli ọmọ Netanaya, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀. Kí ló dé tí o óo jẹ́ kí ó pa ọ́, tí gbogbo Juda tí wọn kóra jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ yóo sì túká; tí àwọn tí wọn ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan Juda yóo sì ṣègbé?”
16. Ṣugbọn Gedalaya sọ fún Johanani, ọmọ Karea pé, “Má ṣe bẹ́ẹ̀, irọ́ ni ò ń pamọ́ Iṣimaeli.”