2. Ní ọjọ́ kẹsan-an, oṣù kẹrin, ọdún kọkanla ìjọba rẹ̀, wọ́n wọ ìlú náà.
3. Lẹ́yìn tí ogun ti kó Jerusalẹmu, gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babiloni péjọ, wọ́n sì jókòó ní bodè ààrin: Negali Sareseri, Samgari Nebo, Sarisekimu Rabusarisi, Negali Sareseri, Rabumagi ati àwọn ìjòyè ọba Babiloni yòókù.
4. Nígbà tí Sedekaya ọba Juda ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ rí wọn, wọ́n sá. Wọ́n fòru bojú, wọ́n bá jáde ní ìlú; wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba, ní ọ̀nà ibodè tí ó wà láàrin odi meji, wọ́n sì dojú kọ ọ̀nà Araba.
5. Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lé wọn, wọ́n bá Sedekaya ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; wọ́n mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Nebukadinesari ọba Babiloni ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, ó sì dá Sedekaya lẹ́jọ́.
6. Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya ní Ribila níṣojú rẹ̀, ó sì pa gbogbo àwọn ìjòyè Juda pẹlu.
7. Ó yọ ojú Sedekaya, ó sì fi ẹ̀wọ̀n bàbà dè é láti mú un lọ sí Babiloni.
8. Àwọn ará Kalidea jó ààfin ọba ati ilé àwọn ará ìlú, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀.
9. Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá kó àwọn eniyan tí wọn ṣẹ́kù ní Jerusalẹmu ní ìgbèkùn, lọ sí Babiloni pẹlu àwọn tí wọn kọ́ sá lọ bá a tẹ́lẹ̀.
10. Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ó sì fún wọn ní ọgbà àjàrà ati oko.