17. Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú un wá sí ààfin rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA ranṣẹ kankan?”Jeremaya dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí OLUWA sọ ni pé, a óo fi ọ́ lé ọba Babiloni lọ́wọ́.”
18. Jeremaya wá bi Sedekaya ọba pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́, tabi àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, tabi àwọn ará ìlú yìí, tí ẹ fi jù mí sẹ́wọ̀n?
19. Níbo ni àwọn wolii rẹ wà, àwọn tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọ pé, ‘Ọba Babiloni kò ní gbógun ti ìwọ ati ilẹ̀ yìí?’
20. Nisinsinyii, kabiyesi, oluwa mi, jọ̀wọ́ fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi, má dá mi pada sí ilé Jonatani akọ̀wé, kí n má baà kú sibẹ.”
21. Sedekaya ọba bá pàṣẹ, wọ́n sì fi Jeremaya sinu gbọ̀ngàn ọgbà àwọn tí ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n sì ń fún un ní burẹdi kan lojumọ láti òpópónà àwọn oníburẹdi títí tí gbogbo burẹdi fi tán ní ìlú. Bẹ́ẹ̀ ni Jeremaya ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbọ̀ngàn àwọn tí ń ṣọ́ ààfin.