24. “Ṣé o kò gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi ń sọ tí wọn ní, ‘OLUWA ti kọ ìdílé mejeeji tí ó yàn sílẹ̀?’ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń fojú tẹmbẹlu àwọn eniyan mi, títí tí wọn kò fi dàbí orílẹ̀-èdè lójú wọn mọ́.
25. Bí n kò bá tíì fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu ọ̀sán ati òru, tí n kò sì ṣe ìlànà fún ọ̀run ati ayé,
26. òun nìkan ni n óo fi kọ arọmọdọmọ Jakọbu ati Dafidi, iranṣẹ mi sílẹ̀, tí n kò fi ní máa yan ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ láti jọba lórí ìran Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. N óo dá ire wọn pada, n óo sì ṣàánú fún wọn.”