Jeremaya 33:19-24 BIBELI MIMỌ (BM)

19. OLUWA tún bá Jeremaya sọ̀rọ̀;

20. ó ní, “Bí ẹ bá lè ba majẹmu tí mo bá ọ̀sán ati òru dá jẹ́, tí wọn kò fi ní wà ní àkókò tí mo yàn fún wọn mọ́,

21. òun nìkan ni majẹmu tí mo bá Dafidi iranṣẹ mi dá ṣe lè yẹ̀, tí ìdílé rẹ̀ kò fi ní máa ní ọmọkunrin kan tí yóo jọba; bẹ́ẹ̀ náà ni majẹmu tí mo bá àwọn alufaa, ọmọ Lefi iranṣẹ mi dá.

22. Bí a kò ti ṣe lè ka iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí a kò sì lè wọn yanrìn etí òkun, bẹ́ẹ̀ ní n óo ṣe sọ arọmọdọmọ Dafidi ati arọmọdọmọ Lefi alufaa, iranṣẹ mi, di pupọ.”

23. OLUWA bi Jeremaya pé:

24. “Ṣé o kò gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi ń sọ tí wọn ní, ‘OLUWA ti kọ ìdílé mejeeji tí ó yàn sílẹ̀?’ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń fojú tẹmbẹlu àwọn eniyan mi, títí tí wọn kò fi dàbí orílẹ̀-èdè lójú wọn mọ́.

Jeremaya 33