Jeremaya 30:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA Ọlọrun Israẹli bá Jeremaya sọ̀rọ̀:

2. Ó ní, “Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún ọ sinu ìwé,

3. nítorí pé àkókò ń bọ̀ tí n óo dá ire àwọn eniyan mi, Israẹli ati Juda pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo mú wọn pada wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì di ohun ìní wọn.”

Jeremaya 30