1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLUWA ń ba yín sọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli:
2. OLUWA ní,“Ẹ má kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ẹ má sì páyà nítorí àwọn àmì ojú ọ̀run,bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tilẹ̀ ń páyà nítorí wọn,
3. nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn àṣà wọn.Wọn á gé igi ninu igbó,agbẹ́gilére á fi àáké gbẹ́ ẹ.
4. Wọn á fi fadaka ati wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,wọn á sì fi ìṣó kàn án mọ́lẹ̀,kí ó má baà wó lulẹ̀.