32. Ati pé darandaran ni wọ́n, ìtọ́jú ẹran ọ̀sìn ni iṣẹ́ wọn, wọ́n sì kó gbogbo agbo mààlúù ati agbo ewúrẹ́, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní lọ́wọ́ wá.
33. Ó ní nígbà tí Farao bá pè wọ́n, tí ó bá bi wọ́n léèrè pé irú iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe,
34. kí wọ́n dá a lóhùn pé, ẹran ọ̀sìn ni àwọn ti ń tọ́jú láti ìgbà èwe àwọn títí di ìsinsìnyìí, ati àwọn ati àwọn baba àwọn, kí ó lè jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé ìríra patapata ni gbogbo darandaran jẹ́ fún àwọn ará Ijipti.