Ìwé Òwe 7:22-27 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e,bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa,tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté,

23. títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninubí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn,láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun.

24. Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi,ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ.

25. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín lọ sọ́dọ̀ irú obinrin bẹ́ẹ̀,ẹ má ṣèèṣì yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

26. Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti sọ di ẹni ilẹ̀,ọpọlọpọ àwọn alágbára ni ó ti ṣe ikú pa.

27. Ọ̀nà isà òkú tààrà ni ilé rẹ̀,ilé rẹ̀ ni ọ̀nà àbùjá sí ìparun.

Ìwé Òwe 7