17. Mo tú turari olóòórùn dídùn ati òjíá, aloe ati sinamoni, sórí ibùsùn mi.
18. Wá, jẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,jẹ́ kí á fi ìfẹ́ gbádùn ara wa.
19. Ọkọ mi kò sí nílé,ó ti lọ sí ìrìn àjò, ọ̀nà rẹ̀ sì jìn.
20. Ó mú owó pupọ lọ́wọ́,kò ní dé títí òṣùpá yóo fi di àrànmọ́jú.”
21. Ó rọ̀ ọ́ pẹlu ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,ó fi ọ̀rọ̀ dídùn mú un.
22. Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e,bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa,tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté,
23. títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninubí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn,láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun.