12. Bí ó ti ń rìn kiri lójú pópó,bẹ́ẹ̀ ni yóo máa lọ, tí yóo máa bọ̀ láàrin ọjà,yóo máa dọdẹ kiri ní gbogbo kọ̀rọ̀.
13. Yóo bá dì mọ́ ọmọkunrin tí kò gbọ́n náà, yóo fi ẹnu kò ó lẹ́nu,yóo wí pẹlu ainitiju pé,
14. “Mo ti rú ẹbọ alaafia,mo sì ti san ẹ̀jẹ́ mi lónìí.
15. Nítorí náà, mo wá pàdé rẹ,mo fi ìlara wá ọ, mo sì rí ọ.
16. Mo ti tẹ́ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláràbarà ti ilẹ̀ Ijipti sórí ibùsùn mi.
17. Mo tú turari olóòórùn dídùn ati òjíá, aloe ati sinamoni, sórí ibùsùn mi.
18. Wá, jẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,jẹ́ kí á fi ìfẹ́ gbádùn ara wa.
19. Ọkọ mi kò sí nílé,ó ti lọ sí ìrìn àjò, ọ̀nà rẹ̀ sì jìn.