Ìwé Òwe 6:26-30 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Owó tí aṣẹ́wó yóo gbà kò ju owó burẹdi lọ,ṣugbọn gbogbo ẹ̀mí rẹ ni alágbèrè yóo fi ọgbọ́n gbà.

27. Ǹjẹ́ ẹnìkan lè gbé iná ka àyà,kí aṣọ rẹ̀ má jó?

28. Tabi eniyan lè rìn lórí ẹ̀yinná,kí iná má jó o lẹ́sẹ̀?

29. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó lọ bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀ rí,kò sí ẹni tí yóo ṣe bẹ́ẹ̀ tí yóo lọ láìjìyà.

30. Ẹnìkan kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jí oúnjẹ jẹ nítorí ebi.

Ìwé Òwe 6