14. Ó ń fi inú burúkú pète ibi, ó sì ń fi ojoojumọ dá ìjà sílẹ̀,
15. nítorí náà, ibi yóo dé bá a lójijì,yóo parun kíá láìsí àtúnṣe.
16. Àwọn nǹkan mẹfa kan wà tí OLUWA kò fẹ́:wọ́n tilẹ̀ tó meje tí ó jẹ́ ohun ìríra fún un:
17. Ìgbéraga, irọ́ pípa,ẹni tí ń déédé pa aláìṣẹ̀,
18. ọkàn tí ń pète ìkà,ẹsẹ̀ tí ń sáré sí ibi,
19. ẹlẹ́rìí èké tí ẹnu rẹ̀ kún fún irọ́,ati ẹni tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin eniyan.
20. Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́,má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
21. Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo,kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.
22. Nígbà tí o bá ń lọ, wọn yóo máa tọ́ ọ,bí o bá sùn, wọn yóo máa ṣọ́ ọ,bí o bá jí, wọn yóo máa bá ọ sọ̀rọ̀.
23. Nítorí fìtílà ni òfin,ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè,
24. láti pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obinrin burúkú,ati lọ́wọ́ ẹnu alágbèrè obinrin tí ó dùn lọ́rọ̀.