Ìwé Òwe 5:10-17 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Kí àjèjì má baà jèrè iṣẹ́ yín,kí làálàá rẹ má sì bọ́ sápò àlejò.

11. Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ,nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni

12. nígbà náà ni o óo wí pé,“Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni,tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí!

13. N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ min kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà.

14. Èyí ni ó sún mi dé etí bèbè ìparun,láàrin àwùjọ eniyan.”

15. Ìwọ ọkọ, láti inú àmù rẹ ni kí o ti máa mu omi;omi tí ń sun láti inú kànga rẹ ni kí o máa mu.

16. Kò dára kí orísun rẹ máa ṣàn káàkiri,bí omi àgbàrá ní gbogbo òpópónà.

17. Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́,má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀.

Ìwé Òwe 5