3. Nígbà tí mo wà ní ọmọde lọ́dọ̀ baba mi,tí mo jẹ́ ẹni ìkẹ́, ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi,
4. baba mi kọ́ mi, ó ní,“Fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn,pa òfin mi mọ́, kí o lè wà láàyè.
5. Jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí o sì ní ìmọ̀.Má gbàgbé, má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.
6. Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́,fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́.
7. Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n,ohun yòówù tí o lè tún ní,ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n.