Ìwé Òwe 30:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọ̀rọ̀ Aguri, ọmọ Jake ará Masa nìyí:Ọkunrin yìí sọ fún Itieli ati Ukali pé,

2. “Nítòótọ́ mo jẹ́ aláìmọ̀kan jùlọ ninu gbogbo eniyan,n kò ní òye tí ó yẹ kí eniyan ní.

3. N kò tíì kọ́ ọgbọ́n,n kò sì ní ìmọ̀ Ẹni Mímọ́.

4. Ta ló ti lọ sí ọ̀run rí, tí ó sì tún pada wá?Ta ló ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ọwọ́ rẹ̀?Ta ló ti fi aṣọ rẹ̀ di omi?Ta ló fi ìdí gbogbo òpin ayé múlẹ̀?Kí ni orúkọ olúwarẹ̀? Kí sì ni orúkọ ọmọ rẹ̀?Ṣé o mọ̀ ọ́n!

Ìwé Òwe 30