18. Igi ìyè ni fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọn,ayọ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí wọ́n dì í mú ṣinṣin.
19. Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀,òye ni ó sì fi dá ọ̀run.
20. Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni ibú fi ń tú omi jáde,tí ìrì fi ń sẹ̀ láti inú ìkùukùu.
21. Ọmọ mi, di ọgbọ́n tí ó yè kooro ati làákàyè mú,má sì ṣe jẹ́ kí wọn bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ,
22. wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ,ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.
23. Nígbà náà ni o óo máa rìnláìléwu ati láìkọsẹ̀.
24. Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́,bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ.
25. Má bẹ̀rù àjálù òjijì,tabi ìparun àwọn ẹni ibi,nígbà tí ó bá dé bá ọ,
26. nítorí pé, OLUWA ni igbẹkẹle rẹ,kò sì ní jẹ́ kí o ti ẹsẹ̀ bọ tàkúté.
27. Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, nígbà tí ó bá wà ní ìkáwọ́ rẹ láti ṣe é.
28. Má sọ fún aládùúgbò rẹ pé,“Máa lọ ná, n óo fún ọ tí o bá pada wá lọ́la,”nígbà tí ohun tí ó fẹ́ wà lọ́dọ̀ rẹ.
29. Má ṣe gbèrò ibi sí aládùúgbò rẹtí ń fi inú kan bá ọ gbé.
30. Má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà láìnídìí,nígbà tí kò ṣe ọ́ níbi.
31. Má ṣe ìlara ẹni ibimá sì ṣe tẹ̀ sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀nà rẹ̀.
32. Nítorí OLUWA kórìíra alárèékérekè,ṣugbọn ó ní igbẹkẹle ninu àwọn tí wọn dúró ṣinṣin.
33. Ègún OLUWA wà lórí ìdílé ẹni ibi,ṣugbọn a máa bukun ibùgbé àwọn olódodo.
34. A máa fi àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn ṣe ẹlẹ́yà, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.