16. Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,ọrọ̀ ati iyì sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀.
17. Ọ̀nà rẹ̀ tura pupọ,alaafia sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀.
18. Igi ìyè ni fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọn,ayọ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí wọ́n dì í mú ṣinṣin.
19. Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀,òye ni ó sì fi dá ọ̀run.
20. Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni ibú fi ń tú omi jáde,tí ìrì fi ń sẹ̀ láti inú ìkùukùu.
21. Ọmọ mi, di ọgbọ́n tí ó yè kooro ati làákàyè mú,má sì ṣe jẹ́ kí wọn bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ,
22. wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ,ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.
23. Nígbà náà ni o óo máa rìnláìléwu ati láìkọsẹ̀.
24. Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́,bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ.
25. Má bẹ̀rù àjálù òjijì,tabi ìparun àwọn ẹni ibi,nígbà tí ó bá dé bá ọ,
26. nítorí pé, OLUWA ni igbẹkẹle rẹ,kò sì ní jẹ́ kí o ti ẹsẹ̀ bọ tàkúté.
27. Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, nígbà tí ó bá wà ní ìkáwọ́ rẹ láti ṣe é.
28. Má sọ fún aládùúgbò rẹ pé,“Máa lọ ná, n óo fún ọ tí o bá pada wá lọ́la,”nígbà tí ohun tí ó fẹ́ wà lọ́dọ̀ rẹ.
29. Má ṣe gbèrò ibi sí aládùúgbò rẹtí ń fi inú kan bá ọ gbé.