Ìwé Òwe 28:10-20 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ẹni tí ó ṣi olódodo lọ́nà lọ sinu ibi,yóo já sinu kòtò tí òun fúnrarẹ̀ gbẹ́ sílẹ̀,ṣugbọn aláìlẹ́bi eniyan yóo jogún ire.

11. Ọlọ́rọ̀ gbọ́n lójú ara rẹ̀,ṣugbọn talaka tí ó gbọ́n yóo rídìí rẹ̀.

12. Nígbà tí olódodo bá borí, àwọn eniyan á yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,ṣugbọn nígbà tí ìkà bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́.

13. Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣe rere,ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,tí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo rí àánú gbà.

14. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó ń bẹ̀rù OLUWA nígbà gbogbo,ṣugbọn ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le yóo bọ́ sinu ìyọnu.

15. Ọba burúkú tí ó jọba lórí àwọn talaka,dàbí kinniun tí ń bú ramúramù,tabi ẹranko beari tí inú ń bí.

16. Ìkà, aninilára ni olórí tí kò ní òye,ṣugbọn ẹ̀mí ẹni tí ó bá kórìíra à ń jèrè lọ́nà èrú yóo gùn.

17. Bí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan bá ń da eniyan láàmú,yóo di ìsáǹsá ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,kí ẹnikẹ́ni má ṣe ràn án lọ́wọ́.

18. Ẹni tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú yóo rí ìgbàlà,ṣugbọn ẹni tí ń rìn ségesège yóo ṣubú sinu kòtò.

19. Ẹni tí ń ṣiṣẹ́ oko dáradára, yóo ní oúnjẹ pupọ,ṣugbọn ẹni tí ń fi àkókò rẹ̀ ṣòfò yóo di talaka.

20. Olóòótọ́ yóo ní ibukun lọpọlọpọ,ṣugbọn ẹni tí ń kánjú àtilówó, kò ní lọ láìjìyà.

Ìwé Òwe 28