9. Òróró ati turari a máa mú inú dùn,ṣugbọn láti inú ìmọ̀ràn òtítọ́ ni adùn ọ̀rẹ́ ti ń wá.
10. Má pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì ati àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ;má sì lọ sí ilé arakunrin rẹ ní ọjọ́ ìṣòro rẹ.Nítorí pé aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni sàn ju arakunrin tí ó jìnnà sí ni lọ.
11. Ọmọ mi, gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn,kí n lè rí ẹnu dá àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi lóhùn.
12. Amòye eniyan rí ewu, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́,ṣugbọn òpè kọjá lọ láàrin rẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.
13. Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,kí o sì gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ rẹ̀,tí ó bá ṣe onídùúró fún àjèjì obinrin.
14. Ẹni tí ó jí ní kutukutu òwúrọ̀,tí ó ń fi ariwo kí aládùúgbò rẹ̀,kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń ṣépè.
15. Iyawo oníjà dàbí omi òjò,tí ń kán tó! Tó! Tó! Láì dáwọ́ dúró;
16. ẹni tí bá ń gbìyànjú láti dá irú obinrin bẹ́ẹ̀ lẹ́kundàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti dá afẹ́fẹ́ dúró,tabi ẹni tó fẹ́ fi ọwọ́ mú epo.
17. Bí irin ti ń pọ́n irin,bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.
18. Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ,ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀.
19. Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni,bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn.
20. Ìparun ati isà òkú kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn,bẹ́ẹ̀ náà ni ojú eniyan, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.
21. Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò,ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò.
22. Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó,kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà,ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.
23. Rí i dájú pé o mọ̀ bí agbo ẹran rẹ ti rí,sì máa tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran rẹ dáradára;
24. nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí,kí adé pẹ́ lórí kì í ṣe láti ìrandíran.
25. Lẹ́yìn tí a bá gé koríko, tí koríko tútù mìíràn sì hù,tí a bá kó koríko tí a gé lára àwọn òkè wálé,
26. o óo rí irun aguntan fi hun aṣọ,o óo sì lè fi owó tí o bá pa lórí àwọn ewúrẹ́ rẹ ra ilẹ̀.