7. Ẹni tí ó yó lè wo oyin ní àwòmọ́jú,ṣugbọn bí nǹkan tilẹ̀ korò a máa dùn,lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.
8. Ẹni tí ó ṣìnà ilé rẹ̀,dàbí ẹyẹ tí ó ṣìnà ìtẹ́ rẹ̀.
9. Òróró ati turari a máa mú inú dùn,ṣugbọn láti inú ìmọ̀ràn òtítọ́ ni adùn ọ̀rẹ́ ti ń wá.
10. Má pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì ati àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ;má sì lọ sí ilé arakunrin rẹ ní ọjọ́ ìṣòro rẹ.Nítorí pé aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni sàn ju arakunrin tí ó jìnnà sí ni lọ.
11. Ọmọ mi, gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn,kí n lè rí ẹnu dá àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi lóhùn.
12. Amòye eniyan rí ewu, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́,ṣugbọn òpè kọjá lọ láàrin rẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.
13. Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,kí o sì gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ rẹ̀,tí ó bá ṣe onídùúró fún àjèjì obinrin.