16. ẹni tí bá ń gbìyànjú láti dá irú obinrin bẹ́ẹ̀ lẹ́kundàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti dá afẹ́fẹ́ dúró,tabi ẹni tó fẹ́ fi ọwọ́ mú epo.
17. Bí irin ti ń pọ́n irin,bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.
18. Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ,ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀.
19. Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni,bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn.
20. Ìparun ati isà òkú kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn,bẹ́ẹ̀ náà ni ojú eniyan, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.
21. Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò,ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò.
22. Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó,kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà,ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.
23. Rí i dájú pé o mọ̀ bí agbo ẹran rẹ ti rí,sì máa tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran rẹ dáradára;