Ìwé Òwe 26:3-21 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Bí pàṣán ti rí lára ẹṣin, tí ìjánu sì rí lẹ́nu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,bẹ́ẹ̀ ni igi rí lẹ́yìn àwọn òmùgọ̀.

4. Má ṣe dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀,kí ìwọ pàápàá má baà dàbí rẹ̀.

5. Dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà agọ̀ rẹ̀,kí ó má baà rò pé òun gbọ́n lójú ara òun.

6. Ẹni tí ó rán òmùgọ̀ níṣẹ́ gé ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀,ó sì ń mu omi ìjàngbọ̀n.

7. Bí ẹsẹ̀ arọ, tí kò wúlò,ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀.

8. Bí ẹni fi òkúta sinu kànnàkànnà,ni ẹni tí ń yẹ́ òmùgọ̀ sí rí.

9. Bí ẹ̀gún tí ó gún ọ̀mùtí lọ́wọ́,ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀.

10. Ẹni tí ó gba òmùgọ̀ tabi ọ̀mùtí sí iṣẹ́dàbí tafàtafà tí ń pa eniyan lára kiri.

11. Bí ajá tíí pada sídìí èébì rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ tó pada sí ìwà agọ̀ rẹ̀.

12. Ìrètí ń bẹ fún òmùgọ̀ju ẹni tí ó gbọ́n lójú ara rẹ̀ lọ.

13. Ọ̀lẹ ń wí pé, “Kinniun kan wà lọ́nà!Kinniun buburu kan wà ní ìgboro!”

14. Bí ìlẹ̀kùn ṣe ń ṣí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ìdè rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ibùsùn rẹ̀.

15. Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ,ṣugbọn ó lẹ kọjá kí ó lè bu oúnjẹ kí ó fi bọ ẹnu.

16. Ọ̀lẹ gbọ́n lójú ara rẹ̀ju eniyan meje tí wọ́n lè dáhùn ọ̀rọ̀ pẹlu ọgbọ́n lọ.

17. Ẹni tí ó ti ọrùn bọ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀,dàbí ẹni tí ó gbá ajá alájá létí mú.

18. Bíi aṣiwèrè tí ó ju igi iná tabi ọfà olóró,

19. ni ẹni tó ṣi ẹlòmíràn lọ́nà,tí ó wá ń sọ pé “Mo kàn ń ṣeré ni!”

20. Láìsí igi, iná óo kú,bẹ́ẹ̀ ni, láìsí olófòófó, ìjà óo tán.

21. Bí èédú ti rí sí ògúnná, ati igi sí iná,bẹ́ẹ̀ ni oníjà eniyan rí, sí àtidá ìjà sílẹ̀.

Ìwé Òwe 26