Ìwé Òwe 25:13-20 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Bí òtútù yìnyín nígbà ìkórè,bẹ́ẹ̀ ni olóòótọ́ iranṣẹ jẹ́, sí àwọn tí ó rán an,a máa fi ọkàn àwọn oluwa rẹ̀ balẹ̀.

14. Bí òjò tí ó ṣú dudu tí ó fẹ́ atẹ́gùn títíṣugbọn tí kò rọ̀,ni ẹni tí ó ń fọ́nnu láti fúnni lẹ́bùn,tí kò sì fúnni ní nǹkankan.

15. Pẹlu sùúrù, a lè yí aláṣẹ lọ́kàn padaọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ eegun.

16. Bí o bá rí oyin, lá a níwọ̀nba,má lá a ní àlájù, kí o má baà bì.

17. Má máa lọ sílé aládùúgbò rẹ lemọ́lemọ́,kí ọ̀rọ̀ rẹ má baà sú u, kí ó sì kórìíra rẹ.

18. Ẹni tí ó jẹ́rìí èké nípa aládùúgbò rẹ̀dàbí kùmọ̀ ọmọ ogun, tabi idà, tabi ọfà tí ó mú.

19. Igbẹkẹle ninu alaiṣootọ ní àkókò ìṣòro,dàbí eyín tí ń ro ni, tabi ẹsẹ̀ tí ó rọ́.

20. Bí ẹni tí a bọ́ṣọ rẹ̀ ninu òtútù,tabi tí a da ọtí kíkan sójú egbò rẹ̀,ni ẹni tí à ń kọrin fún ní àkókò tí inú rẹ̀ bàjẹ́.

Ìwé Òwe 25