Ìwé Òwe 21:13-18 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ẹni tí ó kọ etí dídi sí igbe talaka,òun náà yóo kígbe, ṣugbọn kò ní rí ẹni dá a lóhùn.

14. Ẹ̀bùn tí a fúnni ní kọ̀rọ̀ a máa paná ibinu,àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí a tì bọ abẹ́ aṣọ a máa paná ìjà.

15. Tí a bá ṣe ìdájọ́ òtítọ́, inú olódodo a dùn,ṣugbọn ìfòyà ni fún àwọn aṣebi.

16. Ẹni tí ó sá kúrò lọ́nà òyeyóo sinmi láàrin àwọn òkú.

17. Ẹni tí ó fẹ́ràn fàájì yóo di talaka,ẹni tí ó fẹ́ràn ọtí waini ati òróró kò ní lówó lọ́wọ́.

18. Eniyan burúkú ni yóo forí gba ibitíì bá dé bá olódodo.Alaiṣootọ ni yóo fara gba ìyà tí ó tọ́ sí olóòótọ́ inú.

Ìwé Òwe 21