Ìwé Òwe 20:15-22 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Wúrà ń bẹ, òkúta olówó iyebíye sì wà lọpọlọpọ,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ni ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye.

16. Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tí kò mọ̀ rí.

17. Oúnjẹ tí a bá rí lọ́nà èrú máa ń dùn lẹ́nu eniyan,ṣugbọn nígbà tí a bá jẹ ẹ́ tán, ẹnu ẹni a máa kan.

18. Ìmọ̀ràn níí fìdí ètò múlẹ̀,gba ìtọ́sọ́nà kí o tó lọ jagun.

19. Ẹni tí ó ń ṣe òfófó káàkiri a máa tú ọpọlọpọ àṣírí,nítorí náà má ṣe bá ẹlẹ́jọ́ kẹ́gbẹ́.

20. Bí eniyan bá ń fi baba tabi ìyá rẹ̀ bú,àtùpà rẹ̀ yóo kú láàrin òkùnkùn biribiri.

21. Ogún tí a fi ìkánjú kójọ níbẹ̀rẹ̀,kì í ní ibukun nígbẹ̀yìn.

22. Má sọ pé o fẹ́ fi burúkú san burúkú,gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, yóo sì gbà ọ́.

Ìwé Òwe 20