Ìwé Òwe 19:26-28 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ẹni tí ó bá kó baba rẹ̀ nílé, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde,ọmọ tíí fa ìtìjú ati àbùkù báni ni.

27. Ọmọ mi, bí o bá kọ etí dídi sí ẹ̀kọ́,o óo ṣìnà kúrò ninu ìmọ̀.

28. Ẹlẹ́rìí èké a máa kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́,eniyan burúkú a máa jẹ ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni jẹun.

Ìwé Òwe 19