Ìwé Òwe 19:22-27 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ohun tí ayé ń fẹ́ lára eniyan ni òtítọ́ inú,talaka sì sàn ju òpùrọ́ lọ.

23. Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú ìyè wá,ẹni tí ó ní i yóo ní ìfọ̀kànbalẹ̀,ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí i.

24. Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ,ṣugbọn kò lè bu oúnjẹ sí ẹnu ara rẹ̀.

25. Na pẹ̀gànpẹ̀gàn eniyan, òpè yóo sì kọ́gbọ́n.Bá olóye wí, yóo sì ní ìmọ̀ sí i.

26. Ẹni tí ó bá kó baba rẹ̀ nílé, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde,ọmọ tíí fa ìtìjú ati àbùkù báni ni.

27. Ọmọ mi, bí o bá kọ etí dídi sí ẹ̀kọ́,o óo ṣìnà kúrò ninu ìmọ̀.

Ìwé Òwe 19