Ìwé Òwe 18:18-24 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Gègé ṣíṣẹ́ a máa yanjú ọ̀rọ̀a sì parí gbolohun asọ̀ láàrin àwọn alágbára.

19. Ọkàn arakunrin tí eniyan bá ṣẹ̀ a máa le bí ìlú olódi,àríyànjiyàn sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ilé ìṣọ́.

20. Eniyan lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu wá oúnjẹ fún ara rẹ̀,a lè jẹ oúnjẹ tí a bá fi ọ̀rọ̀ ẹnu wání àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù.

21. Ahọ́n lágbára láti pani ati láti lani,ẹni tí ó bá fẹ́ràn rẹ̀ yóo jèrè rẹ̀.

22. Ẹni tí ó bá rí aya fẹ́ rí ohun rere, ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA.

23. Ẹ̀bẹ̀ ni talaka bẹ̀,ṣugbọn ọlọ́rọ̀ á dáhùn tìkanra-tìkanra.

24. Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà, ọ̀rẹ́ àfẹnujẹ́ ni wọ́n,ṣugbọn ọ̀rẹ́ mìíràn wà tí ó fi ara mọ́ni ju ọmọ ìyá ẹni lọ.

Ìwé Òwe 18