Ìwé Òwe 18:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Onímọ-tara-ẹni-nìkan ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀,láti tako ìdájọ́ òtítọ́.

2. Òmùgọ̀ kò ní inú dídùn sí ìmọ̀,àfi kí ó ṣá máa sọ èrò ọkàn rẹ̀.

3. Nígbà tí ìwà burúkú bá dé, ẹ̀gàn yóo dé,bí àbùkù bá wọlé ìtìjú yóo tẹ̀lé e.

Ìwé Òwe 18