Ìwé Òwe 17:20-22 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ẹni tí ó ní ọkàn ẹ̀tàn kò ní ṣe àṣeyege,ẹlẹ́nu meji yóo bọ́ sinu ìyọnu.

21. Ìbànújẹ́ ni kí eniyan bí ọmọ tí kò gbọ́n,kò sí ayọ̀ fún baba òmùgọ̀.

22. Ọ̀yàyà jẹ́ òògùn tí ó dára fún ara,ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí eniyan rù.

Ìwé Òwe 17