Ìwé Òwe 17:17-21 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,ṣugbọn a bí arakunrin láti dúró tini ní ìgbà ìpọ́njú.

18. Ẹni tí kò bá gbọ́n níí jẹ́jẹ̀ẹ́,láti ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.

19. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀,ẹni tí ó bá fẹ́ràn kí á máa fi owó ṣe àṣehàn ń wá ìparun.

20. Ẹni tí ó ní ọkàn ẹ̀tàn kò ní ṣe àṣeyege,ẹlẹ́nu meji yóo bọ́ sinu ìyọnu.

21. Ìbànújẹ́ ni kí eniyan bí ọmọ tí kò gbọ́n,kò sí ayọ̀ fún baba òmùgọ̀.

Ìwé Òwe 17