22. Orísun ìyè ni ọgbọ́n jẹ́ fún àwọn tí wọn ní i,agọ̀ sì jẹ́ ìjìyà fún àwọn òmùgọ̀.
23. Ọgbọ́n inú níí mú kí ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tọ̀nà,ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa yíni lọ́kàn pada.
24. Ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára dàbí afárá oyin,a máa mú inú ẹni dùn, a sì máa mú ara ẹni yá.
25. Ọ̀nà kan wà tí ó tọ́ lójú eniyan,ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.
26. Ebi níí mú kí òṣìṣẹ́ múra síṣẹ́,ohun tí a óo jẹ ní ń lé ni kiri.
27. Eniyan lásán a máa pète ibi,ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni.
28. Ṣòkèṣodò a máa dá ìjà sílẹ̀,ọ̀rọ̀ àhesọ a máa tú ọ̀rẹ́ kòríkòsùn.