17. Olóòótọ́ kì í tọ ọ̀nà ibi,ẹni tí ń ṣọ́ra, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń pamọ́.
18. Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun,agídí ní ń ṣáájú ìṣubú.
19. Ó sàn kí eniyan jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹlu àwọn talakaju kí ó bá agbéraga pín ìkógun lọ.
20. Yóo dára fún ẹni tí ó bá ń gbọ́ràn,ẹni tí ó bá sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ní ayọ̀.