Ìwé Òwe 14:5-12 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ẹlẹ́rìí òtítọ́ kì í parọ́,ṣugbọn irọ́ ṣá ni ti ẹlẹ́rìí èké.

6. Pẹ̀gànpẹ̀gàn a máa wá ọgbọ́n, sibẹ kò ní rí i,ṣugbọn ati ní ìmọ̀ kò ṣòro fún ẹni tí ó ní òye.

7. Yẹra fún òmùgọ̀,nítorí o kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n lẹ́nu rẹ̀.

8. Ohun tí ó jẹ́ ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́nni pé kí ó kíyèsí ọ̀nà ara rẹ̀,ṣugbọn àìmòye àwọn òmùgọ̀ kún fún ìtànjẹ.

9. Àwọn òmùgọ̀ a máa fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwàdà,ṣugbọn àwọn olódodo a máa rí ojurere.

10. Kálukú ló mọ ìbànújẹ́ ọkàn ara rẹ̀,kò sì sí àjèjì tí ń báni pín ninu ayọ̀.

11. Ìdílé ẹni ibi yóo parun,ṣugbọn ilé olódodo yóo máa gbèrú títí lae.

12. Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí ẹni pé ó tọ́ lójú eniyan,ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.

Ìwé Òwe 14