Ìwé Òwe 14:28-35 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ògo ọba,olórí tí kò bá ní eniyan yóo parun.

29. Ẹni tí kì í báá yára bínú lóye lọpọlọpọ,ṣugbọn onínúfùfù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

30. Ìbàlẹ̀ ọkàn a máa mú kí ara dá ṣáṣá,ṣugbọn ìlara a máa dá egbò sinu eegun.

31. Ẹni tí ó bá ni talaka lára àbùkù Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni ó ń ta,ṣugbọn ẹni tí ó ṣàánú fún àwọn aláìní ń bu ọlá fún Ẹlẹ́dàá rẹ̀.

32. Eniyan burúkú ṣubú nítorí ìwà ibi rẹ̀,ṣugbọn olódodo rí ààbò nípasẹ̀ òtítọ́ inú rẹ̀.

33. Ọgbọ́n kún inú ẹni tí ó mòye,ṣugbọn kò sí ohun tí ó jọ ọgbọ́n lọ́kàn òmùgọ̀.

34. Òdodo ní ń gbé orílẹ̀-èdè lékè,ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹ̀gàn fún orílẹ̀-èdè.

35. Iranṣẹ tí ó bá hùwà ọlọ́gbọ́n a máa rí ojurere ọba,ṣugbọn inú a máa bí ọba sí iranṣẹ tí ó bá hùwà ìtìjú.

Ìwé Òwe 14