26. Ninu ìbẹ̀rù OLUWA ni igbẹkẹle tí ó dájú wà,níbẹ̀ ni ààbò wà fún àwọn ọmọ ẹni.
27. Ìbẹ̀rù OLUWA ni orísun ìyè,òun níí mú ká yẹra fún tàkúté ikú.
28. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ògo ọba,olórí tí kò bá ní eniyan yóo parun.
29. Ẹni tí kì í báá yára bínú lóye lọpọlọpọ,ṣugbọn onínúfùfù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.
30. Ìbàlẹ̀ ọkàn a máa mú kí ara dá ṣáṣá,ṣugbọn ìlara a máa dá egbò sinu eegun.
31. Ẹni tí ó bá ni talaka lára àbùkù Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni ó ń ta,ṣugbọn ẹni tí ó ṣàánú fún àwọn aláìní ń bu ọlá fún Ẹlẹ́dàá rẹ̀.
32. Eniyan burúkú ṣubú nítorí ìwà ibi rẹ̀,ṣugbọn olódodo rí ààbò nípasẹ̀ òtítọ́ inú rẹ̀.
33. Ọgbọ́n kún inú ẹni tí ó mòye,ṣugbọn kò sí ohun tí ó jọ ọgbọ́n lọ́kàn òmùgọ̀.
34. Òdodo ní ń gbé orílẹ̀-èdè lékè,ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹ̀gàn fún orílẹ̀-èdè.
35. Iranṣẹ tí ó bá hùwà ọlọ́gbọ́n a máa rí ojurere ọba,ṣugbọn inú a máa bí ọba sí iranṣẹ tí ó bá hùwà ìtìjú.