Ìwé Òwe 13:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn,ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú.

10. Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà,ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.

11. Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù,ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.

12. Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn,ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.

13. Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun,ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀.

14. Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyèa máa yọni ninu tàkúté ikú.

15. Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere,ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn.

16. Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo,ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn.

17. Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala,ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá.

Ìwé Òwe 13