Ìwé Òwe 12:17-24 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo,ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa.

18. Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.

19. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayéṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni.

20. Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi,ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀.

21. Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo,ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu.

22. OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́,ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́.

23. Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́,ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.

24. Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí,ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá.

Ìwé Òwe 12