Ìwé Òwe 10:7-16 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ayọ̀ ni ìrántí olódodo,ṣugbọn orúkọ eniyan burúkú yóo di ohun ìgbàgbé.

8. Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́,ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun.

9. Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà,ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú.

10. Ẹni tí bá ń ṣẹ́jú sí ni láti sọ̀rọ̀ èké, a máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀,ṣugbọn ẹni tí bá ń báni wí ní gbangba, ń wá alaafia.

11. Ẹnu olódodo dàbí orísun omi ìyè,ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu,a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.

12. Ìkórìíra a máa rú ìjà sókè,ṣugbọn ìfẹ́ a máa fojú fo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dá.

13. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa ń jáde lẹ́nu ẹni tí ó ní òye,ṣugbọn kùmọ̀ ló yẹ ẹ̀yìn ẹni tí kò gbọ́n.

14. Ọlọ́gbọ́n eniyan a máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ máa ń fa ìparun mọ́ra.

15. Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ààbò rẹ̀,ṣugbọn àìní talaka ni yóo pa talaka run.

16. Èrè àwọn olódodo a máa fa ìyè,ṣugbọn èrè àwọn eniyan burúkú a máa fà wọ́n sinu ẹ̀ṣẹ̀.

Ìwé Òwe 10