Ìwé Òwe 10:3-15 BIBELI MIMỌ (BM)

3. OLUWA kì í jẹ́ kí ebi pa olódodo,ṣugbọn ó máa ń da ìfẹ́ ọkàn eniyan burúkú rú.

4. Ìmẹ́lẹ́ máa ń fa òṣì,ṣugbọn ẹni tí ó bá tẹpá mọ́ṣẹ́ yóo di ọlọ́rọ̀.

5. Ọlọ́gbọ́n ní ọmọ tí ó kórè ní àkókò ìkórè,ṣugbọn ọmọ tí ó bá ń sùn lákòókò ìkórèa máa kó ìtìjú báni.

6. Ibukun wà lórí olódodo,ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu,a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.

7. Ayọ̀ ni ìrántí olódodo,ṣugbọn orúkọ eniyan burúkú yóo di ohun ìgbàgbé.

8. Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́,ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun.

9. Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà,ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú.

10. Ẹni tí bá ń ṣẹ́jú sí ni láti sọ̀rọ̀ èké, a máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀,ṣugbọn ẹni tí bá ń báni wí ní gbangba, ń wá alaafia.

11. Ẹnu olódodo dàbí orísun omi ìyè,ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu,a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.

12. Ìkórìíra a máa rú ìjà sókè,ṣugbọn ìfẹ́ a máa fojú fo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dá.

13. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa ń jáde lẹ́nu ẹni tí ó ní òye,ṣugbọn kùmọ̀ ló yẹ ẹ̀yìn ẹni tí kò gbọ́n.

14. Ọlọ́gbọ́n eniyan a máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ máa ń fa ìparun mọ́ra.

15. Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ààbò rẹ̀,ṣugbọn àìní talaka ni yóo pa talaka run.

Ìwé Òwe 10